Ẹgbẹ́ àwọn obìnrin oníròyìn nílẹ̀ Nàijírìa, NAWOJ, ẹ̀ka tìpínlẹ̀ Ọsun, ti késìjọba àtàwọn àjọ tí kíì se tìjọba láti fọwọ́sowọ́pọ̀ lẹ́nu ìgbésẹ̀ fífòpinsí ọ̀kanọ̀jọ̀kan ìwà ipá àti ìkọlù tó ń kojú àwọn obìnrin.

Níbi ètò àyájọ́ ọjọ́ fífòpinsí gbogbo àwọn ìkọlù tón kojú àwọn obìnrin, niwọ́n ti fìdí èyí múlẹ̀.

Alága ẹgbẹ́ NAWOJ, ẹ̀ka tìpínlẹ̀ Ògùn, aráìnrin Modupeọla Sobukọla sàlàyé fáwọn oníròyìn nílu Abẹokuta pé, ẹgbẹ́ náà yóò tẹ̀síwájú láti máà fojú àwọn èeyàn tó bá hu ìwà ipá sáwọn obìnrin han fáyérí.

Ó wá sàlàyé ìdí tó fi sepàtàkì fún ìjọba láti mámugbòorò bá gbogbo àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé lórílẹ̀dè yíì, tó sì rọ àwọn àjọ aláabo gbogbo láti mú ọ̀rọ̀ àwọn tíwọ́n bá gbé ẹjọ́ wọn wá síwájú wọn lọ́kunkúndù, nípasẹ̀ ti tètè dìde sí ìkọlù ọ̀hún.

Arábìnrin Sobukọla rọ àwọn obìnrin láti máà sàtìlẹyìn fúnrawọn kéròngbà wọn lè bá wá sí ìmúsẹ kíwọ́n sì máà yàgò fóhun-kóhun tó bá le jk kí àwọn ọkùnrin máà hu ìwà ipá síwọn.

Agness/Idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *