Ètó ìpolongo àti ìlanilọ́yẹ̀ lórí fífòpinsí ètò abẹ-dídá fọ́mọbìrin nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ lóti sọ èso rere pẹ̀lú bí agbègbè mẹ́rìndínlógójì nìjọba ìbílẹ̀ Ìsẹ́yìn nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, se fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àsà náà tidi ohun àfìsẹ́yìn téegún fisọ.

Èyí tẹlẹ oníruru ètò ìdánilẹ́kọ àti ìpàdé pẹ̀lú àwọn tọ́rọkàn lórí abẹ-dídá, èyítí àjọ olùtanijí sojuse ẹni N.O.A nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ àti àjọ UNICEF gùnlé láwọn agbègbè tásà náà tigògò lọ́dún mẹ́rin sẹ́yìn.

Olùdarí ajọ NOA, nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ arábìnrin Dọlapọ Dosunmu gbóóríyìn fáwọn olórí agbègbè fún àjọ náà pé láipẹ láijìnà òpin pátápátá yóò de bá àsà abẹ́ dídá fọ́mọbìnrin nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ olùdarí àjọ UNICEF, lẹ́kùn ìwọ̀ọorùn ilẹ̀ yíì, arábìnrin Aderonkẹ Olutayọ sọpé, láipẹ ikọ kan yóò jk gbígbékalẹ̀ láti máà tọpinpin àwọn ilé-ìwòsàn, àtàwọn ibùdó ìgbẹ̀bí tófimọ́ sise ìdánilẹ́kọ fáwọn tọ́rọkàn láti fòpin sí àsà àbẹ́ dídá fọ́mọbìnrin.

Sáajú Asẹ́yìn tìlú Ìsẹ́yìn, ọ̀mọ̀wé Abdulgani Adekunle ẹnitó sọdi mímọ̀ pé, òyé ti yé wọn lágbègbè ọ̀hún pé, kòsí ànfàní kankan nínú dídábẹ́ fọ́mọbìnrin èyító ńpè fún síse àtìlẹ́yìn fún bópin yóòse débá.

Àwọn agbègbè tọ́rọkan tọwọ́ bọ fọmu tájọ UNICEF, sì fúnwọn ní ìwé ẹ̀rí.

Kẹhinde/Idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *