Alákoso fọ́rọ̀ ìròyìn àti àsà, Àlhájì Lai Mohammed ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn ilẹ̀ tóti gòkè àgbà láti se àtìlẹ́yìn fún orílẹ̀èdè Nàijírìa pẹ̀lú àwọn irinsẹ́ tó yẹ láti lè wọ̀ yája pẹ̀lú ìgbésùnmọ̀mí.

Ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ yí lásìkò tó se àbẹ̀wò ẹkúsẹ́ ńbẹun sí Gómìnà Samuel Ortom nílèjọba tó wà ní Markurdi.

Àlhájì Muhammed sọ pé ìgbésùmọ̀mí jẹ́ ìpèníjà tó ń bá gbogbo àgbáyé fínra ìdínìyí tó fi yẹ kí àwọn orílẹ̀ èdè lágbayé se àtìlẹ́yìn fún Nàijírìa lórí o n èlò láti gbógun ti ìgbésùnmọ̀mí.

Alakoso sàpèjúwe, ìkọlù tó wáyé láipẹ yi nípinlẹ̀ Borno èyí tí wọ́n ní ikọ̀ Boko haram ló wà nídi ìkọlù náà, níbití ọ̀pọ̀ èyàn ti jẹ́ pípa gẹ́gẹ́bí èyí tókùdiẹ káto ó wá sèlérí pé ilẹ̀ yí yo tẹ̀síwájú láti ma sa gbogbo ipá rẹ̀ láti dábobo ẹ̀mí àti dúkia àwọn èyàn àwùjọ.

Jibikẹ/Afọnja        

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *