Àwọn tó fẹ́ gba ìtọ́jú kúrò lọ́wọ́ àrùn kókóró HIV nílèwòsàn ìjọba Heart to Heart nílu ọ̀yọ́ ńfẹ́ kí àmúbgòrò débá ètò ìgbáyégbádùn èyí tí ẹ̀ka tikise tìjọba gbé kalẹ̀, láti lèjẹ́ kí wọ́n lè borí ìpèníjà ètò ọrọ ajé tó ń bá ill yí fínra.

Lára àwọn tó ní àrùn yí tó bá akọ̀ròyìn ilésẹ́ Radio Nigeria sọ̀rọ̀, sọpé pẹ̀lú bí àdínkù se débá on tí àwọn àjọ tikise tìjọba pèsè bi on tẹ́nuńjẹ , àti owó ọkọ̀ tin sàkóbá fún ọ̀pọ̀ wọn.

Nínú ọ̀rọ̀ olùdarí àjọ tikise tìjọba kan nílu ọ̀yọ́, Bishọbu àgbà Ayọ Ladigbolu sàlàyé pé, bótilẹ̀jẹ́pé lára àwọn àjọ yi ti dáwọ́ ọrẹ wọn dúró, àmọ́ àjọ tí òun léwájú rẹ̀, sin pèsè on ìdẹ̀rùn, bótilẹ̀jẹ́pé bọ́wọ́ eku ti mọ ló se fin rọrí.

Ó wá rọ gbogbo èyàn tówà lágbègbè náà láti lọ se àyẹ̀wò kòkòrò HIV, látìgbàdégbà , wípé àwọn yo sì tẹ̀síwájú nínú ni náàwọ́ ọrẹ sí wọn.

Àkọ́ọ̀sílẹ̀ fihàn pé ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àwọn tóní àrùn yí tón lọ gba ìtọ́jú ní Heart to heart Clinic láti bi ọdún mẹ́rin sẹ́yìn.

Oguntọna/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *