Olúwo ti Ìwóm ọba Abdulrasheed Akanbi ti fi àidùnú rẹ̀ hàn lórí bí wọ́n ti se àwárí bùba ajínigbé sètùtù ní agbègbè rẹ̀.

Ọba Akanbi nínú àtẹ̀jáde tó fi síta ni ó jẹ́ ohuntí ó yani lẹ́nu pé àwọn ènìyàn ìlú Ìwó sì léè pani sètùtù lẹ́yìn gbogbo ìpolongo rẹ̀ lórí dídẹ́kun irú ìwà ibi bẹ́ẹ̀.

Ó wá rọ àwọn àjọ elétò àabò láti sisẹ́ ìwádi wọn dójú àmìn lórí ìsẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Ọba Akanbi ẹnití ó ní Ìwó jẹ́ ìlú tí wọ́n mọ̀ mọn mí mọrírì ẹ̀mín ènìyàn tó wà ní ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá mú pé ó ńta ẹ̀yà ara ènìyàn ni kí wọ́n fọwọ́ ti wọn fi ńmu ọ̀daràn mu.

Ọba alayé náà ni wọ́n yio sàgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ aláabo kan tí yio ma jẹ́ alagàta láàrin ìlú àti àwọn òsìsẹ́ aláabo láti léè máà ta wọ́n lólobó bí wọ́n bá kẹ́ẹ́fín ìwà ìpani finisètùtù èyíkèyí.

Ajadosu/Dada Yẹmisi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *