Àwọn tọ́rọkàn nídi bíbójútó ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ti pè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ará ìlú nídi ríri pé wọ́n tètè dìde ìrànwọ́ lásìkò tí ìjàmbá bá wáyé lágbègbè wọn.

Wọ́n fìpè yí síta níbi ìdánilẹ́kọ ọlọ́gọ́ méjì lórí bíbójútó ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbà èyítí àjọ àabò ara ẹni làabò ìlú, NCDC, ẹ̀ka tìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ sagbátẹrù rẹ̀.

Igbákejì ọ̀gá àgbà àjọ tó ńbójútó ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, NEMA lẹ́kùn yí, ọ̀gbéni adebiyi Babatunde mẹ́nuba ìgbáradì, dídìde wuya, àti sísàtúnse gẹ́gẹ́bí àwọn èròjà láti mún àdínkù bá ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá.

Bákanà, alámojútó ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá nínú àjọ alágbelébu pupa, ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Fadeyi Akintọmiwa ni gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ ri àmójútó ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá gẹ́gẹ́bí ojúse láti léè mú àdínkù bá bí o ti se ńfẹjú.

Ní ti ẹ̀, alákoso fọ́rọ̀ àyíká nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Idowu Oyeleke ni gbígbé ìgbésẹ̀ tó gbọngbọ́n yio se ọ̀pọ̀ ìrànwọ́ láti mú àdínkù bá ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá èyíkèyí.

Nígbàtí ó ńkede ìbẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọ náà ọ̀gá àgbà àjọ àabò ara ẹni lààbò ìlú nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbéni Iskilu Akinsanya ni ètò náà se pàtàkì fún àwọn òsìsẹ́ àjọ ọ̀hún láti léè jẹ́kí wọ́n lóye ìlànà láti bójútó àwọn ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì.

Àkòrí ìdánilẹ́kọ ọlọ́jọ́ méjì náà ni sígbàgbékalẹ̀ àwọn ìlànà tó gbọngbọ́n lórí àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá láti mú àdínkù bá ewu tó rọ̀ mọ́ọ̀.

Makinde/Dada Yemisi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *