Yoruba

Alákoso Tẹ́lẹ̀ Fétò Ìsúná, Ngozi Okonjo Iweala Fọọkàn Àwọn Èèyàn Ilẹ̀ Yí Balẹ̀ Lórí Ìpèsè Abẹ́rẹ́ Àjẹsára Covid-19

Alákoso tẹ́lẹ̀ fétò ìsúná, ọ̀mọ̀wé Ngozi Okonjo iweala ti fọwọ́ sọ̀yà fàwọn èèyàn ilẹ̀ yíì àtàwọn orílẹ̀èdè ilẹ̀ Africa tókù lóórí ìpèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára fárùn covid-19, láti ìparí osù kini ọdún tónbọ̀.

Ó sọ̀rọ̀ yíì lẹ́yìn ìpàdé alátìlẹ̀kùmọ́rí se pẹ̀lú alákoso fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkòrè, ọ̀gbẹ́ni Geoffrey Onyeama nílu Abuja.

Ọmọwe Okonjọ Iweala, tise asojú àjọ ìsọ̀kan ilẹ̀ adúláwọ̀ lórí wíwá àtìlẹ́yìn àwọn ilẹ̀ òkèrè nídi ìgbésẹ̀ gbígbógunti àrùn covid-19 kéde pé ìlànà ilẹ̀ òkèrè yíì ní iléwòsàn àjọ elétò ìlera lágbayé W.H.O àti àgbàríjọ àwọn orílẹ̀dè àgbáyé, nídi gbíbgáradì fún àjàkálẹ̀ àrùn niwọ́n ti fẹnukò láti kó àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára lọ sáwọn orílẹ̀dè tó se nse ńdìde lẹ àtàwọn tóò kúrẹtẹ̀ lọ́nà tí ó gáà jara lọ.

Ó fikun pé, lọ́wọ́-lọ́wọ́ báyíì wọ́n ti ń dúna-dúrà lórí báwọn orílẹ̀dè tó kù diẹ káto fún yóò sẹ̀sẹ̀ tètè rí abẹ́rẹ́ náà gbà lái ni tóò lẹ́yìn àwọn orílẹ̀dè tó ti làmì laka.

Net/Elizabeth Idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *