Ìjọba àpapọ̀ ti pèsè owó tó lé ní billiọnu méjìlá naira fáwọn ilé-isẹ́ olókowò kékèké àti talábọ́dé, n’ípasẹ̀ àwọn ilé ìfowófamọ́ olókowò, gẹ́gẹ́ bí ara akitiyan láti pinwọ́ ìpalára ti ìbẹ́sílẹ̀ àrùn covid-19 sokùnfà rẹ̀.

Alákoso ilé-isẹ́ okòwò àti ìdásẹ́alé sílẹ̀, ọ̀gbẹ́ni Niyi Adebayọ tó sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ níbi àpérò kan tó wáyé nílu Abuja, tọ́kasi pé, ìjọba ń sán gbogbo ọ̀nà láti fẹsẹ̀ ìpèsè ǹkan ranlẹ̀ àti dídènà idarudapẹ láwọn ọjà nípasẹ̀ ìpèsè owó náà.

Alákoso ọ̀hún kò sài tọ́kasí pé, ìjọba àpapọ̀ si tún pinu lọ́kàn rẹ̀ láti sàmúlò èróngbà ìlànà àgbẹ́kẹ̀lé ètò ọrọ ajé tó dúró sínú owó náà ké sáwọn ìjọba ìpínlẹ̀ náà láti sàtìlẹ́yìn fún ìjọba àpapọ̀ lẹ́nu gbogbo ìgbésẹ̀ rẹ̀.

Blessing Okareh/Ọlọlade Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *