Alága ẹgbẹ́ àwọn Gómìnà nílẹ̀ yíì, ọ̀mọ̀wé Kayọde Fayẹmi ti pè fún àtúntò ohun àmúsọrọ̀ láarin àwọn ẹ̀ka ìjọba gbogbo nítorí ìdàgbàsókè ilẹ̀ yí lápapọ̀.

Ó pèpè yí níbi ètò àpérò ọlọ́dọdún ẹlẹẹkẹta iruẹ, tó fi mọ́ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún kọkànléláadọrin lẹ́yìn ìpapodà, èyí tó wáyé fún Gómìnà àná nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ológbe Abiọla Ajimóbi ní gbọ̀ngàn àpérò ńlá ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìbàdàn.

Gómìnà Fayẹmi tó tọ́ka sí ojúse ìpínlẹ̀ nínú ìsọkan àti ìdàgbàsókè orílèdè wí pé kíì se kèrémí, ó sọ̀rọ̀ di mímọ̀ pé, ó pọn dandan láti túnbọ̀ gbé agbára wọ àwọn ìjọba ìpínlẹ̀.

Alága ẹgbẹ́ àwọn ẹgbẹ́ Gómìnà náà tẹnumọ́ pé ìjọba ìpínlẹ̀ ti kó ipa lọ́lọ́kan òjọ̀kan láarin abala bíì ètò ààbò, isẹ́ àgbẹ̀, ètò ẹ̀kọ́, ètò ìlera, ìpèsè óunjẹ, léyi tó fi sepàtàkì fún àtúntò ilẹ̀ yí lọ́nà àgbékalẹ̀ ètò ìsèjọba rere.

Sáajú ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó nígbà kan rí, ẹni tíì tún se asíwájú ẹgbẹ́ òsèlú APC, nílẹ̀ yí, Bọla Tinubu nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípasẹ̀ igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Ọbafẹmi Hamzat, ẹni tó pè fún ìjọba àarin gbùngbùn tóòto nípa bó se sọ pé agbára tó wà laarin ti pọ̀ jù.

Àarẹ àjọ Abiọla Ajimọbi, ọ̀mọ̀wé Flọrence Ajimọbi sàlàyé wí pé ètò àpérò náà ló jẹ́ ìtẹ́sẹ́wájú àlà ọkọ òun tó ti dolégbe.

Àwọn èekàn àwùjọ, àwọn ọba alayé àtàwọn Gómìnà ìpínlẹ̀ ló péjú síbi ètò náà.

Net/Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *