Yoruba

Alákoso ọ̀rọ̀ abẹ́lé kọminú lórí owó ribiribi fún ìpèsè káàdi ìdánimọ̀ ilẹ̀ yí

Aákoso fọ́rọ̀ abẹ́lé nílẹ̀ yí, ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹgbẹsọla ti sọ̀rọ̀ di mímọ̀ pé, káàdi ìdánimọ̀ ill yí tuntun fáwọn ọmọ ilẹ̀ yí yóò na ìjọba ní òbítíbitì owó.

Ọgbẹni Arẹgbẹsọla sípaya ọ̀rọ̀ yí fáwọn oníròyìn nílu ilésà pẹ̀lú wí pé number fún káàdi ìdánimọ̀ ilẹ̀yí tó se pàtàkì lákokò yí fún gbogbo ọmọ ilẹ̀ yí ni wọ́n léè pèsè lai náwó lórí ìpèsè káàdi.

Alákoso ọ̀rọ̀ abẹ́lé tẹnumọ pé ẹnu bodè ilẹ̀ yi ni áàbò tó péye wà nípa ìpèsè ẹ̀rọ tó n àyẹ̀wò bí èèyàn se jẹ́ sí gbogbo ẹnu àbáwọlé ilẹ̀ yí.

Ó wá se àfikún wípé bíjọba se sí ẹnu bodè ilẹ̀ yí padà ko se pe kí wọn máà kó ọjà tí kò bófin mu wọlé, àti pé gbogbo ọjà tí wọn ko bá pèsè larin orílẹ̀èdè apá ìwọ̀ orùn ilẹ̀ africa nìjọba si fi òfin dè.

Salaudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *