Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì ọ̀mọ̀wé Kayọde Fayẹmi ti tẹnumọ́ ìdí tó fi yẹ kí àtúntò ó wáyé lórí ọ̀nà fáwọn ọmọ ilẹ̀ yí yóò fi ní ìgbọkànlé nínú ilésẹ́ ọlọ́pa wípé àti se àseyọrí nínú ìpèsè ètò ààbò àwùjọ gbérù, léyi tó níì se pẹ̀lú àwọn àjọ elétò àabò àwọn òsìsẹ́ ìjọba, àwọn olósèlú àtàwọn ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́, àwọn ọ̀dọ́ àti ẹgbẹ́ àwọn obìnrin, pẹ̀lú àwọn olórí ilésẹ́ ìjọba nílu Adó-Èkìtì.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì wá rọ gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kàn pé kí wọ́n fẹwọ́ sowọ́pọ̀ lórí àgbékalẹ̀ ètò àabò àwùjọ láti kojú ọ̀rọ̀ báwọn agbésùnmọ̀mí àwọn ajínigbé àtàwọn min-in  tó ń dúnkokò mọ́ ètò àabò àwùjọ ilẹ̀ yí.

Gómìnà tẹnumọ pé ètò àabò a[wùjọ sepàtàkì láti fi kojú ìpèníjà tí ń kojú ilẹ̀ yí, ó tún korò ojú si bí wọ́n ko se ti se àtúnse àbá tó ti wáyé láti bíì ogún ọdún sẹ́yìn wípé bí àtúntò se léè bá ilésẹ́ ọlọ́pa ilẹ̀ yí.

Salaudeen  

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *