Yoruba

Àarẹ orílẹ̀dè yíì, Muhammadu Buhari ti sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, ìsèjọba òun ti n wójùtú sọ́rọ̀ ilégbe fáwọn ọmọ orílẹ̀dè yíì, papajùlọ àwọn tó ń gbé láwọn ìlú ńlánlá.

Lákokò tó ń sèfilọ́lẹ̀ àwọn isẹ́ àkànse ilégbe, abala àkọ́kọ́ nílu Òsogbo, tí sólùlú ìpínlẹ̀ Ọsun, áàrẹ sísọ lójú ọ̀rọ̀ náà.

Áàrẹ Buhari ẹnití alákoso fọ́rs abẹ́lé, ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹgbẹsọla sujúfún tọ́kasi pé, ọ̀pọ̀ àwọn ìlú ńlánlá náà lójẹ́ pé wọ́n ti kún àkúnfàya léyi tó lòdìsí ètò ìlera tó múná dóko, ìdí sìnìyí, tí sèjọba rẹ̀ fi gùnlé isẹ́ àkànse kíkọ́ ilégbe tí yóò rọrùn.

Àarẹ kò sài fikun pé, ọ̀kan pàtàkì ni isẹ́ àkànse òhun jẹ́ lára àwọn ọ̀nà tísèjọba òun ti piyamọ kalẹ̀, láti mú ìgbéayé rọrùn fáwọn èèyàn , gẹ́gẹ́ olókóòwò kékèké àti talábọ́dé ló gba ise àkànse ilé kíkọ́ náà.

Ó ní isẹ́ àkànse ilé kíkọ́ náà ti fún ìjọba àpapọ̀ lánfàní nínú àwọn ìlérí tó ti se tẹ́lẹ̀ se, nípasẹ̀ pípèsè ilégbe fáwọn ikọ̀ agbábbọ̀ọ̀lù Super Eagles lẹ́yìn tíwọ́n jawé olúborí níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ adúláwọ̀ tọdún 1994 èyí tó mú àseyọ́rí bá ìjọba níwọ̀n ko ti se àmúsẹ.

Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ, náà, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọsun, ọ̀gbẹ́ni Adegboyega Oyetọla dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ ìjọba àpàpọ̀, tún  ise àkànse ọ̀hún èyí tóní yóò sàtìlẹ́yìn fún ìjọba ìpínlẹ̀ Ọsun láti pèsè ibùgbé tówó rẹ̀ kòní gunpá fáráàlú rẹ̀.

Net/Wojuade   

Yoruba

Aákoso fọ́rọ̀ abẹ́lé nílẹ̀ yí, ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹgbẹsọla ti sọ̀rọ̀ di mímọ̀ pé, káàdi ìdánimọ̀ ill yí tuntun fáwọn ọmọ ilẹ̀ yí yóò na ìjọba ní òbítíbitì owó.

Ọgbẹni Arẹgbẹsọla sípaya ọ̀rọ̀ yí fáwọn oníròyìn nílu ilésà pẹ̀lú wí pé number fún káàdi ìdánimọ̀ ilẹ̀yí tó se pàtàkì lákokò yí fún gbogbo ọmọ ilẹ̀ yí ni wọ́n léè pèsè lai náwó lórí ìpèsè káàdi.

Alákoso ọ̀rọ̀ abẹ́lé tẹnumọ pé ẹnu bodè ilẹ̀ yi ni áàbò tó péye wà nípa ìpèsè ẹ̀rọ tó n àyẹ̀wò bí èèyàn se jẹ́ sí gbogbo ẹnu àbáwọlé ilẹ̀ yí.

Ó wá se àfikún wípé bíjọba se sí ẹnu bodè ilẹ̀ yí padà ko se pe kí wọn máà kó ọjà tí kò bófin mu wọlé, àti pé gbogbo ọjà tí wọn ko bá pèsè larin orílẹ̀èdè apá ìwọ̀ orùn ilẹ̀ africa nìjọba si fi òfin dè.

Salaudeen