Yoruba

Ijoba Ipinle Osun F’ofinde Iso Oru Aisun Odun, Lati Dena Itankale COVID-19

Ijoba ipinle Osun ti fi ofin de iso oru eyi ti awon ile ijosin tabi egbe maa ngunle lati bo sinu odun tuntun.

Akowe ijoba, Ogbeni Wole Oyebamiji lo je koro yi di mimo ninu atejade to fisita nilu osogbo, pelu atokasi pe ijoba ti pa lase pe kawon osise eto abo gbogbo fese ofin naa mule, lai yo ijo kankan sile.

Ogbeni Oyebamiji so pe ase yi lo waye, alti le dena itankale arun COVID-19.

O wa ro awon olugbe ipinle osun lati din ipejopo won ku, kadinku le deba ifarakinra pelu eni to ti ni corona virus papa pelu bawon ajeji yo se ma wo ipinle naa lasiko odun to gbode yi.

Ololade Afonja/Lara Ayoade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *