News Yoruba

Ijoba Ipinle Osun ni awon metala lo ti je Olorun nipe nitori aisan to ni ise pelu arun covid-19 laarin ojo meje seyin.

Atejade latoodo alakoso foro iroyin ati ilaniloye lori ojuse nipinle Osun, Arabinrin Funke Egbeyemi gba awon olugbe ipinle naa lamonran lati maser o wipe arun covid 19 ko si mo nipinle Osun.

O ni ipinle Osun lo nkoju ijarayin-ranyin ajakale arun naa fun igba keta eyiti bi eya Delta re to ntete ran muki o lagbara.

Atejade naa wa kilo fawon eeyan lati se ojuse won nidi didaabobo ara won ati awon molebi won nitoripe kikoti ikun sawon liana ilere lori re yi muki o tubo maa gbemi awon eniyan.

O fikun wipe ijoba yio tesiwaju lati fikun isapa re nidi igbogunti ajakale arun naa ati ipa to lee ni lori ipinle ohun ati awon are ilu to wa ni awon eeyan gbodo maa tele awon liana ilera lati dena itankale re.

Adenitan/Owonikoko

Yoruba

Ijoba ipinle Osun ti fi ofin de iso oru eyi ti awon ile ijosin tabi egbe maa ngunle lati bo sinu odun tuntun.

Akowe ijoba, Ogbeni Wole Oyebamiji lo je koro yi di mimo ninu atejade to fisita nilu osogbo, pelu atokasi pe ijoba ti pa lase pe kawon osise eto abo gbogbo fese ofin naa mule, lai yo ijo kankan sile.

Ogbeni Oyebamiji so pe ase yi lo waye, alti le dena itankale arun COVID-19.

O wa ro awon olugbe ipinle osun lati din ipejopo won ku, kadinku le deba ifarakinra pelu eni to ti ni corona virus papa pelu bawon ajeji yo se ma wo ipinle naa lasiko odun to gbode yi.

Ololade Afonja/Lara Ayoade