Yoruba

Soun Gboriyin Fun Ijoba Apapo Lori Idasile Ile-Eko Gbogbonise Nipinle Oyo

Soun ti Ogbomoso, Oba Oladunni Oyewumi, Ajagbungbade keta, ti gboriyin fun Aare Muhammadu Buhari pelu bo se b’uwolu idasile ile eko gbogbonise t’oje t’ijoba apapo ni Ayede, Ogbomoso.

Ijoba apapo lenu loloyi, buwolu idasile ile-eko gbogbonise nipinle Oyo, pelu owo ibere ise tooto bilionu meji Naira.

Ninu atejade kan, Oba Oyewumi enito sapejuwe igbese naa gege bi eyi to daa gbaa, gbe osuba kaare fun ijoba.

Oba Oyewumi lasiko to n ki awon omobibi ilu Ogbomoso ku oriire, lori aseyori yii, kesi ijoba ni gbogbo eka lati mu eto eko lokun-kundun.

Oba alaaye ohun, wa rawo ebe sawon ara agbegbe Ayede, lati fowosowopo pelu awon igbimo to nsise ile-eko ohun ti yoo maa sabewo si agbegbe naa fun eto eko toye koro.

Net/Elizabeth Idogbe

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *