Tag: Aare Muhammadu Buhari

  • Aare Buhari Setan Lati Sin Awon Iko Ile Nigeria Ninu Idije Tokyo Olympic Soko

    Ojo Aje Monday to nbo yii ni Aare Muhammadu Buhari yio gbe awon iko elere idaraya tile Nigeria, to nlo fun idije Tokyo Olympic lalejo nile ise Aare to wa nilu Abuja, koto dipe awon isi togbehin awon io ohun yio gbera kuro lorile ede Nigeria lo sibi eto idije naa.

    Alakoso foro awon odo ati idagbasoke ere idaraya nileyi, Ogbeni Sunday Dare, lo so oro ohun di mimo nilu Abuja, lakoko tiwon nse ayeye idagbere ranpe fawon isi akoko awon iko elere idaraya naa kiwon to gbera losi orile ede Japan.

    O sope awon iko ohun niwon yio gbera ni isise ntele nipele merin, ni Aare Buhari yio se ikini idagbere fun lojo Aje to nbo gegebi ara asa ati ise ileyi fawon elere idaraya.

    Alakoso ere idaraya ohun tun salaye pe ayeye naa yio tun fun Aare lanfani lati fa waon iko elere idaraya tile Nigeria fun awon igbimo idije Olympic ni ibamu pelu botiwa lati ojo pipe wa.

    Ogbeni Sunday Dare, tun safomo oro pe Aare Buhari yio tun safihan aso idaraya toje tawon iko elere idaraya ile Nigeria to nlo fun idije Olympic.

    Ni bayina orileede England niyio ma wako pelu orileede Denmark labala tokangun si ase kagba idije ere boolu alafesegba Euro 2020 to n lo lowo.

    Folakemi Wojuade

  • Aare Muhammadu Buhari Fi Afikun Owo Aba Isuna Sowo S’ile Asofin Agba

    Aare orileede yi Muhammadu Buhari ti taari afikun owo bi eedegberun billion naira sinu aba eto isuna odun 2021, si iwaju ile.

    Igbimo Asofin Agba, ninu iwe kan tare Buhari ko ranse, sile Asofin Agba ohun, eyi tiwon ka nibere ijoko ile to waye, lo ti so pe, afikun owo naa lo wa fun owona eto Abere Ajesara to n dena arun Covid-19 eyi ton lowo.

    O salaye pe, lara awon inkan tiwon yoo tun lo owo naa fun ni itoju awon eeyan be egberun lona aadota to wa labe eto itoju kokoro arun AIDS nile yii, yika awon ipinle.

    Aare ko sai fikun pe, aba eto isuna ohun yoo tun seranwo lati safikunb awon irinse tiwon n lo fun gbigbogun tokan o jokan ipeniha to n koju ile Nigeria.

    Folakemi Wojuade

  • Soun Gboriyin Fun Ijoba Apapo Lori Idasile Ile-Eko Gbogbonise Nipinle Oyo

    Soun ti Ogbomoso, Oba Oladunni Oyewumi, Ajagbungbade keta, ti gboriyin fun Aare Muhammadu Buhari pelu bo se b’uwolu idasile ile eko gbogbonise t’oje t’ijoba apapo ni Ayede, Ogbomoso.

    Ijoba apapo lenu loloyi, buwolu idasile ile-eko gbogbonise nipinle Oyo, pelu owo ibere ise tooto bilionu meji Naira.

    Ninu atejade kan, Oba Oyewumi enito sapejuwe igbese naa gege bi eyi to daa gbaa, gbe osuba kaare fun ijoba.

    Oba Oyewumi lasiko to n ki awon omobibi ilu Ogbomoso ku oriire, lori aseyori yii, kesi ijoba ni gbogbo eka lati mu eto eko lokun-kundun.

    Oba alaaye ohun, wa rawo ebe sawon ara agbegbe Ayede, lati fowosowopo pelu awon igbimo to nsise ile-eko ohun ti yoo maa sabewo si agbegbe naa fun eto eko toye koro.

    Net/Elizabeth Idogbe

  • Ifilole Oko Ojurin Ti Yoo Maa Na Ilu Eko Silu ‘Badan Yo Waye Losu Tonbo

    Alakoso f’oro irinna, Ogbeni Rotimi Amaechi sope oko oju irin ti yoo ma naa, ilu eko si ibadan ni yo setan fun ifilole losu tonbo.

    O soro yi ninu iforowanilenuwo pelu awon akoroyin nilu Abuja.

    Alakoso ni oun ti fi oro ifilole naa to Aare Muhammadu Buhari leti, pelu atokasi pe ise akanse ohun ni won ma se de opin apapa, ko to di asiko ifilole.

    Ogbeni Amaechi so pe koni si adinku kankan ninu owo to won yo ma gba lowo awon onibara, to ba ge gun oko oju irin, eyi to pe mewa niye ti won yo si se ifilole re lekan soso ninu osu to nbo.

    Ololade Afonja/Lara Ayoade

  • Ìjọba Kéde Ìlànà Ìkánilọ́wọ́kò Tuntun Lórí Àrùn COVID-19

    Àarẹ Muhammadu Buhari ti pàsẹ kí wọ́n ti àwọn ilé otí, àwọn ilé ijó àti àwọn ibùdó ayẹyẹ tó fi mọ́ àwọn ibùdó ìgbafẹ́ fún ọ̀sẹ̀ márun láti léè dènà ìtànkálẹ̀ àrùn COVID-19.

    Ó tún pàsẹ kí wọ́n ti àwọn ilé óunjẹ ìgbàlódé nígbàtí àwọn ilé ìwé yio wà ni títì títí di ọjọ́ kejìdínlógún osù kíní ọdún 2021.

    Alága ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá ìjọba àpapọ̀ lórí àrùn COVID-19, Ọ̀gbẹ́ni Boss Mustapha ló sọ̀rọ̀ yí lásìkò ìpàdé oníròyìn tí ìgbìmọ̀ náà se.

    Gẹ́gẹ́bí ó se sọ, gbogbo àwọn òsìsẹ́ ìjọba láti ìpele kejìlá sísàlẹ̀ ni wọ́n ti pàsẹ kí wọ́n fìdí mọ́lé fọ́sẹ̀ márun.

    Ọgbẹni Mustapha ẹnití se akswé ìjọba àpapọ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn tó ńrìn ìrìn àjò ni wọ́n ó tẹ̀lé àwọn ìlànà ààbò COVID-19 léyití ó múkí iná ètò àyẹ̀wò àti ìfimúfílẹ̀ lórí àrùn náà jó àjó rẹ̀yìn.

    Yẹmisi Dada

  • Aare Buhari fowosi idasile igbimo kan tonise pelu akanda eda

    Aare orileede yii, Muhammadu Buhari ti fowosi idasile igbimo ati iyansipo akowe, fun ajo to n ri soro awon akanda eda.

    Ninu Atejade kan, t’olubadamoran pataki faare f’eto iroyin ati ibaraalu soro, Ogbeni Femi Adesina, s’ope igbese bibuwolu iyansipo naa nise pelu ideyesi tawon Akanda Eda maa n koju , n’ibamu pelu ofin odun 2019.

    Gege bi ofin naa se lakale pe, eniti yoo  maa dari Ajo naa ni Alaga kan, ati igbimo Eleni mefa tiwon yoo je Akanda Eda lati maa soju ekun idibo to nbe nile yii, pelu ireti lilo odun merin-merin Lori eto akoso won.

    Akowe Ajo naa to yoo je Akanda Eda pelu ireti lilo odun marun-un lori ipo akoso, ni yoo lanfani lilo saa keji, tiwon ba tun yan, Amo, ti ko sanfani fun saa keta.

    Folakemi Wojuade