Yoruba

Àjọ NCC setán láti sàfikún ibùdó ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì lẹ́ka ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀

Àjọ tón rí sétò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ nílẹ̀ yíì, NCC, sọ pé òun sisẹ́ takuntakun láti sàgbékalẹ̀ àwọn ibùdó tí yóò máà rísí ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì lẹ́ka ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láwọn ìpèníjì níbití kò ti sàwọn ohun èlò kankan lọ́wọ́lọ́wọ́ báyíì.

Igbákejì alága àjọ NCC, ọ̀gbẹ́ni Umar Danbatta ló sọ̀rọ̀ ytíì di mimọ̀ lákokò tón gbawọn àmì ẹ̀yẹ méjì kan látilẹ̀ òkèrè.

Ó tọ́kasi pé mọ́kàndílógún ibùdó náà tájọ NCC, ti sèdásílẹ̀ rẹ̀ sáwọn ìpínlẹ̀ méjìdílógún yíká orílẹ̀èdè yíì, ló ti ńkó pa takuntakun lẹ́ka ìgbésẹ̀ pàjáwìrì látọ̀dọ̀ tíwọ́n bá ti tẹ óòkan, óòkan, àtèjì lórí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ wọn, niwọ́n si ri ìdáhùn lẹ́yẹ òsakà.

Ó wá ké sáwọn àjọ tón dáhùn sí ìbéère ìpè náà, láti tọwọ́ àwọn ajọ aláàbo bíì ilé-isẹ́ ọlọ́pa àjọ ẹ̀sọ́ ojú pópó, tàbò araẹni láàbòlú, tílésẹ́ panápaná, àtàjọ tónrísí ìsẹ́lẹ́ pàjáwìrì tófimọ́ àwọn èyí tó dàbí rẹ̀ bọwu ìlànà ìdáhun sí ìpè pàjáwìwì náà.

Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *