Yoruba

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin kejì pè fún ìfikùnlukùn láti yanjú áàwọ̀ àwọn darandaran àtàwọn agbègbè tón gbawọn lálejò

Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin kejì, ọ̀gbéni Fẹmi Gbajabiamila ti pè fún ìpàdé kan, lórí ọ̀nà láti wójùtú sọ́rọ̀ àwọn tó ń wáyé láàrin àwọn darandaran àtàwọn agbègbè tón gbawọn lálejò lápá àríwá orílẹ̀èdè yíì, kó tó di pé ọ̀rọ̀ burú kọjá bó se yẹ.

Ìlú Abuja lọ̀gbéni Gbajabiamila ti sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ pẹ̀lú àlàyé pé, ẹkùn ìwọ̀ óòrùn gúsù ko gbodọ di gbogbo ọ̀rọ̀ ru apá àríwá, bẹ́ẹ̀ náà si ni, àríwá ko gbọdọ eya lo gbọdọ máà bọ́wọ́ fún rawọn nípasẹ̀ okòòwò, itan tófimọ́ àsà kóówá.

Kò sài tọ́kasi pé, ọ̀rọ̀ tóníse pẹ̀lú ìwà ọ̀daràn, páàpajùlọ ìwà ìpànìyàn gbọdọ lọ sópin ìgbàgbé.

Ọgbẹni Gbajabiamila tó gbóríyìn fún ìyànsípò àwọn ọ̀gá aláàbo tuntun látọ̀dọ̀ àarẹ Buhari sàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tó se àtẹ́wọ́gbà kò sài fikun pé, ilé ìgbìmọ̀ àpapọ̀ setán láti pèsè ààyè ìrọ̀rùn fún wọn láti fi sisẹ́ wọn dójú àmì.

Blessing/Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *