News Yoruba

Awon Osise Ajo Olomi Ero Fehonu Han Nilu Ibadan

Awon osise ijoba ti ofisi won wa ninu Ogba Secretariat nilu Ibadan ni won koju isoro lati wo ile ise ijoba loni pelu bi won ti se fi awon oko to je ti ajo Olomi ero di awon enu iloro ibe.

Bi won ti di awon enu iloro yi lo mu ki nkan pakaso pelu bi o ti se uori si sunkere-fakere oko lagbegbe ibe.

Die lara awon onise ajo olomi ero ni won le googogo senu ona ile ijoba ti won si ko jale lati ba akoroyin ile ise Radio Nigeria soro, ti won si ti awon akole bi “nibo ni billionu  kan naira to wa fawon eroja itomi se wa “e doola awon osise ajo olomi ero lowo ei ati ise” “E ma demi ajo olomi ero logbodo ati beebe lo se awon enu ona ile ise ijoba leso.

Awon osise ajo eleto aabo naa o gbehin nibe lati ti wipe alaafia joba.

Lose die seyin ni awon osise ajo olomi ero nipinle Oyo ti gunle iyanselodi lati fi beere fun awon eto won.

Busari/Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *