Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde ti pálásẹ pé kí ọjà sásá níjọba ìbílẹ̀ Akinyẹle sì padà lẹ́yẹ ọ̀sọkà, ọjà ọ̀hún ni wọ́n gbé tì pa lẹ́yìn tí rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ lárin àwọn onilẹ àtàwọn tó wá sisẹ́ níbẹ̀.

Ó pa àsẹ yi lẹ́yìn ìjóko àláfìa tó wáyé lárin Seriki sasa, àlhájì Haruna Maiyasin, Baalẹ agbègbè sasa álhájì Amusq Ajani àtàwọn tọ́rọ̀ kan gbọ̀gbọ̀n ní gbọngan western Secretariat ìbàdàn.

Gómìnà Makinde se lálàyé pé òun gbé ìgbésẹ̀ láti sí ọjà yí padà kí kárà-katà lè bẹ̀rẹ̀ ní sansan, kó sì ma mú kí ìfàsẹ́yìn dé bá ètò ọrọ̀ ajé àwọn  ọlọ́jà, papa jùlọ nígbàtí gbogbo igun tọ́rọ̀kan ti gbà láti ma gbé pọ̀ lálafìa.

Sájú Baalẹ sasa àti seriki sasa nínú ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀wọn  gbẹnu àwọn òntàjà tọrọ àforíjì lórí ìsẹ̀lẹ̀ tó wáyé ọ̀hún, tí wọ́n sì sèlérí láti sisẹ́ ri dájú pé àláfìa àti ìbásepọ̀ láisi ìkùnsínú ńwáyé lọ́jà sasa.

Adebisi/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *