Kòdín ní àwọn olùgbé ìlú Abẹokuta tó jẹ́ àdọ́ta níye tí wọ́n ti fún ní ìjìyà láti sisẹ́-ìlú fún ọjọ́ méjì lẹ́yìn tí wọ́n jẹ̀bi níwájú ilé ẹjọ́ alágbeká pàtàkì ti ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn gbé kalẹ̀ lórí fífi ẹsẹ̀ òfin dídènà covid 19, múlẹ̀, èyí tón pọ̀si lẹ́nu lọ́lọ́ọ́ yi.

Ìgbìmọ̀ tón fi ẹsẹ̀ òfin múlẹ̀ èyí tí alákoso fọ́rọ̀ àsà àti ìrìnàjò afẹ́ nípinlẹ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni Oluwatoyin Taiwo lé wájú rẹ̀, sọpé àwọn arálu ni kò tẹle àwọn òfin àti ìlànà yi bó se yẹ, lómú kí wan se àgbékalẹ̀ ilé ẹjọ́ pàtàkì yi.

Ìpínlẹ̀ Ògùn ti ni àkọlé o le ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́rin, ẹni tí wọ́n ti ní àrùn covid 19 wọ́n ti yọnda èyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún tárawọn ti yá mẹ́ta nígbàtí àwọn mẹ́rìndínladọta bá àrùn náà rin, láti ọdún tó kọjá tó ti bẹ́ sílẹ̀.

Oluokun/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *