Ikọ̀ amúsẹ́yá ìjọba àpapọ̀ fárùn covid 19 ti sèkìlọ̀ fáwọn èèyàn ilẹ̀ yíì, láti ma kíyesara kí ilẹ̀ Nàijírìa má ba kojú àrùn covid-19, fún ìgbà kẹta.

Akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ títún se alága ikọ̀ amúsẹyá ìjọba àpapọ̀ fárùn covid-19, P.T.F, ọ̀gbẹ́ni Boss Mustapha ẹnitó sọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ yíì nílu Abuja, sọpé kòsí ẹnikẹ́ni to ti, léè fakanbalẹ lórí àarùn yíì pẹ̀lú bí abẹ́rẹ́ àjẹsára covid-19 se ti wà ńta.

Ọgbẹni Mustapha, sàlàyé pé, orílẹ̀dè italy, faranse, àti Germany, jẹ́ ara àwọn orílẹ̀èdè tó ti ń kojú àjàkálẹ̀ àrùn covid 19 ẹlẹteta.

Alága ikọ̀ PTF, tọ́kasi pé ètò abẹ́rẹ́ àjẹsára ti bẹ̀rẹ̀ èyí lómú se pàtàkì fáwọn èèyàn láti mú ètò àbò arawọn lakunkúndùn.

Ẹwẹ, olùdarí àgbà , àjọ tó ńrísí ìdàgbàsókè ètò ìlera alábọ́dé nílẹ̀ yíì, Díkítà Faisal Shuaub fikun pé kòtọ́sì ipa kóòtóò abẹ́rẹ́ àjẹsára àrùn covid-19, fáwọn tó ti gbà.

Net/Idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *