Yoruba

Ajo isokan agbaye bere fun billionu kan dollar fun awon tolugbadi igbesunmomi

 Ajo isokan agbaye ti bere fun  igbese iko owo to to billion kan dollar ti se owo ile okere jo lati fi se iranlowo fun awon aeniyan to le ni million mefa ni ekun ariwa ila orun, to fi mo awon eniyan ti isele kan tabi omiran ti si ni ipo pada lati ara rogbodiyan .

 Owo naa  ni won ni,  won yo lo fun iran lowo awon eniyan ton gbeni ekun ariwa ila  orun  lawon ipinle bii, borno, adamawa ati yobe.

Agbenu so fun ajo isokan agbaye ni eka ton ri si soro igbaye gbadun  omoniyan  ogbeni  jens laerke , salaye pe , wahala ati idamu ti ogunlogo awon eniyan  ton gbe ni awon agbegbe ti rogbodiyan tin waye naa, ki se kekere  to si nilo akiyesei loorin .

 Ko sai fi kun pe , ole ni million marun awon eniyan to wa ninu ewu ebi pipa  nitori idarudapo ton waye , eyi ti ibesile arun covid 19 tun se akoba fun    patapata nitori  ofin konile o gbe ile .

 Nibayina, eka ton ri si oro  ounje lagbaye jabo pe , isoro ebi pipa ati awon ipenija ti awon eniyan ton gbeni apa ariwa ile yii nkoju tin pe fun amojuto pajawiri ki oro ma ba buru koja bo se ye .

Agbenuso eka naa, ogbeni  tomson phiri tokasi pe , rogbodiyan to waye lawon ekun tan wi yi lon dena awon eniyan kuro ni idi ogbin ounje eyi to yori si ebi .

Ajibike/wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *