News Yoruba

Àwọn Osise Tó Wà Láwọn Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Àti Ògùn Ti Gùnlé Ìyansẹ́lódì Aláinigbèdéke.

Gbogbo ǹkan ló pakasọ lówurọ òní nílé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ nítorí bágbe àwọn òsìsẹ́ ẹ̀ka ilé ìgbìmọ̀ asòfin nípinlẹ̀ yíì, se gba ẹnu ọ̀nà àbáwọlé sílé ìgbìmọ̀ asòfin náà tìpa.

Ìgbésẹ̀ yíì ló wáyé níbamu pelu olùfẹ̀hóhàn tíwọ́n gùnlẹ̀ èyí tíwọ́n fin bèèrè fómìnira ètò ìsúná fáwọn asòfin ọ̀hún.

Oníròyìn ilé-isẹ́ Radio Nigeria, tó wà níbùdó ilé ìgbìmọ̀ asòfin ọ̀hún, jábọ̀ pé, lọ́pọ̀ yanturu làwọn ẹgbẹ́ náà tújàde, lẹ́nu olùfẹ̀hóhàn wọn ọ̀hún, tíwọ́n sì gbé ilẹ̀kùn tìpa.

Àwọn olùfẹ̀hóhàn náà, tíwọ́n wọ asọ aláwọ̀ pupa pelu onírunru àkọlé lọ́wọ́, bi ótitó gẹ́ẹ̀, ẹ fún ẹ̀ka asòfin lómìnira ètò ìsúná rẹ̀.

Alága ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́ nílé ìgbìmọ̀ asòfin ilẹ̀ yíì, ọ̀gbẹ́ni Yẹmi Alade, sàlàyé pé, ẹgbẹ́ náà gùnlẹ̀ ìyansẹ́lódì aláinigbèdeke láti fi bèèrè sísàmúlò òfin káwọn èyí táàrẹ fọwọ́sí lọ́dún tókọjá.

Kò sài fikun pé, bílẹ̀ Nàijírìa yóò bá fojú gáanní ìsèjọba àwarawa tóòtọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ fún gbogbo ẹ̀ka ìjọba lómìnira ètò ìsúná rẹ̀.

Ọgbẹni Alade sọ pé, ìyansẹ́lodì ọ̀hún yóò tẹ̀síwájú títí dìgbà tíjọba bá ń dáhun sí ìbeere àwọn.

Bákanà, lọmọ sorí nílé asòfin ìpínlẹ̀ Ògùn, níbi tí wọ́n tigbé ilẹ̀kùn ilé asofin tiwọn náà tìpa, tẹ́gbẹ́ náà sì pè fún ìyansẹ́lódì gbogbogbò fáwọn osise ilẹ̀ yíì.

Ogunyẹmi/Wojuade   

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *