Yoruba

Ìjọba Àpapọ̀ Kéde Ọjọ́ Ẹtì Àtọjọ́ Ajé Tónbọ̀ Gẹ́gẹ́bí Ọjọ́ Ìsinmi L’ẹ́nusẹ́

Ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀dè yíì ti kéde ọjọ́ ẹtì ọ̀sẹ̀ yíì àtọjọ́ ajé ọ̀sẹ̀ tónbọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi lẹ́nusẹ́, láti fi sàmì ayẹyẹ ọdún àjínde, fún tọdún yíì.

Alákoso f’ọ́rọ̀ Abẹ́lẹ́, Ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹgbẹsọla ló kéde bẹ́ẹ̀ lórúkọ ìjọba àpapọ̀ nínú àtẹ̀jáde kan t’ólùdarí fétò ìròyìn àtọ̀rọ̀ tójẹmọ́ tàwùjọ nílésẹ náà, Ọ̀gbẹ́ni Mohammed Manga, fisita.

Ọgbẹni Aregbẹsọla wá rọ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi láti máà wàwòkọ́se àwọn ìwà tí Jesu Kristi fikọni, bí nínú ẹ̀mí ìfẹ́, ìdáríjìn, súùru àti ìjẹ́ olùfẹsẹ àláfìa múlẹ̀, nígbà ayé rẹ̀.

Alákoso náà kò sài gbàwọ́n mímọ̀ràn láti lo àkókò náà fi gbàdúrà fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ àláfìa, ìsọ̀kan àti ìlọsíwájú orílẹ̀dè yíì, tó sì fọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà pé, ìjọba àpapọ̀ tún sakitiyan látiridájú pé, ìwà ìjínigbé dohun ìgbàgbé nílẹ̀ Nàijírìa.

Folakemi Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *