Yoruba

Ọdún Àjínde: Àjọ NSCDC Kó Àwọn Òsìsẹ́ Rẹ̀ Tó Lé Lẹ́gbẹ̀rún Méjì Síta

Àjọ ààbò ara ẹni láàbò ìlú, NSCDC, nípinlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti kó àwọn òsìsẹ́ rẹ̀ tó tó ẹgbẹ̀rún méjì àbọ̀ ló si tibu tóòro ìpínlẹ̀ yi láti ríì dájú pé kò sí àayè fún ìwà ọ̀daràn lásìkò pọ̀pọ̀sìnsìn ọdún ajinde.

Àtẹ̀jáde ti agbẹnusọ àjọ náà nípinlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Oluwọle Olusẹgun fi síta nílu Ìbàdàn sọ wípé kíkó àwọn òsìsẹ́ wọn lọ sí gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ mktẹ̀ẹ̀tàlélọ́gbọ̀n àti ìjọba ìbílẹ̀ ondagbasoke márùndínlógójì tó wà nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ se pàtàkì láti léè jẹ́kí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi se ayẹyẹ ọdún ajinde pẹ̀lú ìfọkànbàlẹ̀.

Rasheedah Makinde/Folakemi Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *