Yoruba

Ajo Isokan Ile Europe Kede Atileyin Forilede Nigera Lati Gbogun ti Igbesunmomi

Ajo Isokan Ile Europe ti sofun ijoba apapo wipe gbigbogunti igbesunmomi, laapaa ariwa ila oorun ati awon ipenija leka abo jakedado ile yii, koja fifi awon omo ogun sowo sawon agbegbe ti ipenija waye.

Nigba to nba awon oniroyin soro, saaju ayeye ojo Europe fun todun yii, olori iko ile europu sorilede Nigerai, ati ajo ECOWAS , Ogbeni Ketil Karlse sope ipenija to nba eka abo finra nile Nigeria, fihan pe yato sii lilo awon omo ologun, lati kooju awon agbesunmomin, iforojomitoro oro ati amulo ofin kogbodo je yiyo kuro.

Ogbeni Karlsel so pe ajo isokan ile europ koni kaare nidi ipasepo ati ifowosowopo pelu orilede Nigerai, ti yio situn ma tesiwaju lati gbaruku ti orilede yii nidi wiwa ojutusi oniruru ipenija atawon anfani miran.

Idogbe

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *