Ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀dè yíì ti sún àsẹ máà sisẹ́ rẹ̀ wá látilé fáwọn òsìsẹ́ ọba tó wá lákàsọ̀ kejì la sísàlẹ̀ síwájú si, gẹ́gẹ́bí ara ìgbésẹ̀ láti dènà ìtànkélẹ̀ kòkòrò àrùn covid-19 ẹlẹkeji nílẹ̀ Nàijírìa.

Gẹ́gẹ́ bálámojútó tó wà fọ́rọ̀ kòkòrò àrùn náà, nílẹ̀ yíì, ọ̀gbẹ́ni Mukhtar Mohammed sesọ níbi ìpàdé àwọn oníròyìn tó wáyé nílu Abuja pé, àwọn òsìsẹ́ ìjọba yóò sì tẹ̀síwájú lẹ́nu ìgbésẹ̀ máà sisẹ, rẹ̀ wa látilé, bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kọkànlá osù kẹfà, ọdún yíì lẹ́yìn èyí niwọ́n ni wọ́n tún sàgbéyẹ̀wò rẹ̀ padà.

Óní ó sepàtàkì fúnjọba láti dènà fífi ẹ̀mí àwọn èèyàn sòfò nílẹ̀ Nàijírìa.

Ọgbẹni Mohammadu wá sọpé, ìgbésẹ̀ kónílé ógbélé orooru bẹ̀rẹ̀ látòru àná, ni yóò máà bẹ̀rẹ̀ látáàgo méjìlá òru sáàgo mẹ́rin ìdájí lójóòjúmọ́.

Ọgbẹni Mohammadu wá sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, àwọn àjọ aláàbo pátá gbọ́dọ̀ jígìrì sí ojúse báyíì, láti máà fẹsẹ òfin máà múlẹ̀ daindain.

Omolola Alamu/Folakemi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *