Yoruba

Ẹgbẹ́ Elépo Rọ̀bì Àtafẹ́fẹ́ Gáasi Gbé Ìkìlọ̀ Kalẹ̀ Láti Máà Yọwọ Ìrànwọ́ Kúrò Lórí Epo

Ẹgbẹ́ àwọn elépo rọ̀bì àtafẹ́fk gáasi nílẹ̀ yíì, NUPENG, sọpé àmọ̀ràn ìgbìmọ̀ olùgbaniníyàjú lórí ètò ọrọ ajé tilé sẹ́ àarẹ, gbékalẹ̀ láti ìjáwọ́ ìrànwọ́ orí epo pẹtirol niwọ́n ni yóò kan tún pakún ìsòro tílẹ̀ Nàijírìa ńkojú.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìgbésẹ̀ náà, akọ̀wé àgbà àjọ NUPENG, ọ̀gbẹ́ni Olawale Alabi sọ fáwọn oníròyìn pé sísàmúlò àmọ̀ràn tígbìmọ̀ olù gbékalẹ̀ yóò kan tún mú kín kan nira fáwọn aráàlu, pẹ̀lú ipò tétò ọrọ ajé ilẹ̀ Nàijírìa wa lọ́wọ́lọ́wọ́ báyíì.

Ọgbẹni Afọlabi kò sài tọ́kasi pé ẹgbẹ́ náà ti tẹnumọ sáàjú fún ìjọba àpapọ̀ pé, kò gbọdọ̀ jẹ́ ori gbigbe epo wọlé náà, niwọ́n yóò ti yọwọ́ ìrànwọ̀ orí epo níkíkún .

Bẹ́ẹ̀ ló sun yíyọwọ́ ìrànwọ́ náà lẹ́ka epo rọ̀bì kò bójúmu tó nítirípé, ilẹ̀ Nàijírìa kò gbọ gbérúfẹ́ ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ lákokò tíwọ́n ń kó epo wọlé sílẹ̀ yíì.

Omolola Alamu/Folakemi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *