Yoruba

Ìpínlẹ̀ Èkó ti gbé àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́rìnlá sábẹ́ àmójútó láti dènà ìtànkálẹ̀ ẹ̀yà àrùn covid tuntun

Gẹ́gẹ́bí ara ọ̀nà láti dènà kí àrùn covid 19 tuntun bẹ́ sílẹ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti fi àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́rìnlá kan sábẹ́ àmójútó tó péye.

Alákoso fétò ìlera nípinlẹ̀ Èkó, ọ̀jọ̀gbọ́n Akin Abayọmi, ló sọ̀rọ̀ yí lásìkò tón bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, óní ìgbésẹ̀ yi ló se pàtàkì lẹ́yìn tí wọ́n sàwárí ẹ̀yà àrùn covid tuntun, láwọn orílẹ̀ èdè ọ̀hún.

Ọjọgbọn Abayọmi sọpé ìpínlẹ̀ Èkó yo ma mójútó ìrìnsí àwọn èyàn láti ilẹ̀ Canada, America, France, Cameroun, Angola, South Africa, Kenya, Uganda, Tanzania tófimọ́ Rwanda.

Alákoso fikun pé, ìpínlẹ̀ Èkó yo ri dájú pé àwọn èyàn ilẹ̀ Nàijírìa tónbọ̀ láti Umura lọ farapamọ́ fún ọjọ́ méje, óní ìjọba yo fìyà tó tọ́ fẹ́ ẹni tó bá kọ̀ láti tẹ̀lé àsẹ yi.

Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *