Àrẹ Muhammadu Buhari ti késí àwọn èyàn nílẹ̀ Nàijírìa láti tẹ̀síwájú nínú wíwà láfifìa, ìsọ̀kan àti fífi ìfẹ́ hàn léyi tí wọ́n gùnlé lásìkò osù Ramadan.

Àrẹ sọ̀rọ̀ yí nínú ìwé tó fi síta nípasẹ̀ agbẹnusọ rẹ̀ Mallam Garba Shehu nílu Abuja.

Àrẹ Buhari kí gbogbo èyàn ilẹ̀ yi pátápátá, tófimọ́ àwọn mùsùlùmí yíká àgbáyé kú ọdún ìtúnu àwẹ̀ pẹ̀lú bí wọ́n ti se parí àwẹ̀ osùkan ti Ramadan.

Gẹ́gẹ́bí Àrẹ tiwí wíwà nísọ̀kan laifi ti ẹ̀sìn kówá se, ó se pàtàkì papa lásìkò yí tórílẹ̀ èdè Nàijírìa kojú oníruru ìpèníjà.

Àrẹ wá rọ̀ wọ́n, láti tẹ̀síwájú nínú títẹ̀lé gbogbo ìlànà tóndènà àrùn covid 19 papa lásìkò ìtúnu àwẹ̀ yí.

Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *