News Yoruba

Àjọ NSCDC Bèèrè Àtìlẹyìn F’awọn Asọgbo Ọba

Àjọ ààbò ara ẹni láàbò ìlú NSCDC, ti ńbèèrè fún àtìlẹyin àwọn ará ìlú láti léè túbọ̀ síse wọn bíì isẹ́.

Ọga àgbà àjọ NSCDC, nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Iskilu Akinsanya ló sọ̀ro yí lásìkò tó sàbẹ̀wò isọwọ síse àwọn asogbo ọba láti ìgbàtí wọ́n ti sèfilọ́lẹ̀ rẹ̀ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ tó wáyé ní olú ilé isẹ́ àjọ náà l’ádugbò nílu ìbàdàn.

Ọgbẹni Akinsanya wòye pé ìdásílẹ̀ ikọ̀ àwọn asọ́gbé ọba ló wáyé lásìkò tó tọ́ tí ilẹ̀ yí ńkojú ìpèníjà lórí ọ̀rọ̀ ọ̀gbìn àti ọ̀sìn ẹran láti léè túbọ̀ kún ìpèsè óunjẹ lọ́wọ́.

Ó wá gbóríyìn fún atilẹyin tí wọ́n fún àwọn asogbo ọba yi ni Sẹpẹtẹri tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ ìwọ̀ óòrun Sakiníbití wọ́n ti pèsè àwọn irinsẹ́ tó yẹ fún wọn láti máà pararo àwọn oko toto ọ̀tàlélọ́ọ̀dunrún ó lé márun tó wà lagbegbese náà lọ́nà àti dáàbòbò àwọn àgbẹ̀ tó ń sisẹ́ lórí oko.

Ọga àgbà àjọ náà ọ̀gbẹ́ni Akinsanya tún késí àwọn olóko ọ̀gbìn ńlá ńlá àti àwọn tọ́lọrun bẹ́gi ọlà fún bílẹ̀ yí láti sàwòkọ́se irú ìwà àwọn èèyàn sẹ̀pẹ̀tẹ̀rí, kí wọ́n fáàyè gba àwọn asọ́gbó ọba láàye àti túbọ̀ sisk sìn wọ́n nídi ìpèsè óunjẹ lọ́pọ̀ yanturu nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ àti nílẹ̀ yí lápapọ̀.

Dada/Makinde

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *