News Yoruba

Gómìnà Seyi Makinde Sèlérí Ìpèsè Irinsẹ́ Fáwọn Àjọ Elétò Áàbò Nípinlẹ̀ Ọ̀yọ́

ómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde ti sèlérí àti ró àwọn àjọ elétò áàbò lágbára síì láti léè sisẹ́ dójú àmìn láti léè jẹ́kí àláàfìa jọba nípinlẹ̀ yi.

Ó sèlérí ọ̀rọ̀ yí níbi ìsìn ìdúpẹ́ láti fi sàmì ayẹyẹ ọdún méjì rẹ̀ lórí ipò Gómìnà èyítí ó wáyé nínú ìjọ Peteru mímọ́ tó wá l’áremọ nílu ìbàdàn.

Gómìnà Makinde tẹnumọ́ọ̀ wípé àwọn àjọ elétò áàbò nílò àwọn irinsẹ́ ìgbàlódé láti léè sisẹ́ tí wọ́n gbé le wọn lọ́wọ́ lórí dídáàbòbò ẹ̀mí àti òun dúkia, tó wá rọ àwọn ènìyàn láti tẹramọ́ àdúrà fún àseyọ́rí ìjọba tó wà lóde báyi.

Nínú ìwásù rẹ̀, Àlúfà ìjọ Peteru mímọ́ Aremọ, ẹniọwọ Adewale Adebiyi sàpèjúwe ìdúpẹ́ gẹ́gẹ́bí mímọrírì Ọlọ́run tó wa rọ àwọn ènìyàn láti mu àsà ìdúpẹ́ lọ́kunkúndùn láti réè ri ànfàní tó pọ jẹ.

Lára àwọn èèyàn tó pese sí ibi ètò ìdúpẹ́ náà láti ri akọ̀wé ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, arábìnrin Olubanwo Adeọsun, olórí àwọn òsìsẹ́ lọ́fìsì Gómìnà, Olóyè Bisi Ilaka, igbákejì rẹ̀, ọ̀gbẹ́ni Abdulmjeed, Mogbonjubọla, olori àwọn òsìsẹ́, arábìnri Amidat Agboola àti àwọn lọ́galọ́ga lẹ́nu isẹ́ ìjọba.

Adebisi/Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *