Ajọ eléto ìdìbò ill yí INEC, ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìforúkọ olùdìbò padá, ní ìpalẹ̀mọ́ fún ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2023.
Alága àjọ elétò ìdìbò nílẹ̀ yí, ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood Yakubu sọ̀rọ̀ yí di mímọ̀ pẹ̀lú àlàyé wípé àjọ náà ti se àlékún ibúdò tuntun, èyí tí wọ́n si ti se adayanri ẹlẹ́gbẹ́jẹ́gbẹ́ bíì mọ́kànlẹ́lọ́gbọ̀n ti yóò tọpinpin bí ètò náà bá se ńlọ sí.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ́n Yakubu se wí, ètò ìforúkọsílẹ̀ náà èyí tí ń wáyé fún bíì ọdún kan ó lé ní òun lérò pe wọn yóò ti se ìforúkọsílẹ̀ olùdìbò tuntun bíì ogún milliọnu.
Alága àjọ elétò ìdìbò wá sèlérí àti fi kélé òfin gbé ẹni yowu tó bá se ohun tó lòdì sófin ní gbogbo àkókò tí ètò náà yóò fi wáyé.
Ó tún sàlàyé wípé àjọ náà ti pèsè ààyè fáwọn tí wàhálà le kuro nílẹ̀ léyi tó se se kí wọ́n ti sọ káàdi ìdìbò alálòpẹ́ wọn nù nípasẹ̀ ètò ààbò tó mẹ́hẹ.
Alága àjọ elétò ìdìbò tẹnumọ ìdí tó fi yẹ kí mu ètò ìpolongo ni ọ̀kúnkúndùn, káwọn olùdìbò léè mọ̀ àwọn ibùdó ètò ìdìbò tuntun t;i wọn dá sílẹ̀ sáàgú kétò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2023 tó wọlé dé.

Net /Salaudeen   
pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *