Yoruba

Àjọ SON, kìlọ̀ fáwọn iléesẹ́ tó ń pèsè irin tútù lórí àmójútó irin-isẹ́ nítorí àwùjọ

Àjọ tó ń rí sí ìpeniye ǹkan ìlò nílẹ̀ Níajírìa SON, ti sèkìlọ̀ fáwọn iléésẹ́ tó ń pèsè irin pé kí wọ́n mójútó àwọn irin-isẹ́ tí wọ́n ńlò fún ìpèsè irin.

Olùdarí àgbà àjọ SON, ọ̀gbẹ́ni Farouk Salim tó sípayá ọ̀rọ̀ yí níbi àpéjọpọ̀ kan tó wáyé nílu Abuja sọ́ọ̀ di mímọ̀ pé àjọ náà ti se àlàkalẹ̀ ìlànà lórí irin-isẹ́ tí wọ́n gbọdọ náà tẹlẹ.

Ó tọ́ka si pé àjọ SON kojú osuwọn láti máà se atọ́nà lórí iri-isẹ́ tí wọ́n gbọdọ̀ máà lò láwọn iléèsẹ́ bíì èyí ti ń pèsè irin-tutu, iléèsẹ́ ojú omi pẹ̀lú iléèsẹ́ èròjà epo rọ̀bì àti afẹ́fẹ́ gáàsi.

Ọgbẹni Salim tún sọ́ọ̀ di mímọ̀ pé gbogbo ǹkan ti wọn fi ń se òdiwọ̀n àti àwọn irin-isẹ́ tí wọ́n ń lò níléèsẹ́ tó ń pese asọ ni wọn gbọdọ máà tọpinpin wọn, kí ohun gbogbo le máà lọ déèdé.

Babatunde Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *