News Yoruba

Àwọn Omímọ̀ Nípa Ètò Ẹ̀kọ́ Fẹ́ẹ̀ Kíjọba Gbọn Wọ́ Sí Ẹnawo Ẹ̀ka Ètò Ẹ̀kọ́

Níbáyí tílẹ̀ Nàijírìa ń darapọ̀ mọ́ ilẹ́ àgbáyé tókù fún sísàmìn àyájọ́ ọjọ́ mọ́ọ̀kọ mọ́ọ̀kà lágbayé fún tọdún 2021 àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan lẹ́ka tón rísí ètò ẹ̀kọ́ àgbà, àti ẹkọ́ kíkọ́ọ̀ lailai, fk kí ìjọba gbọnwọ́ sí ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́.

Wọ́n sọ̀rọ̀ náà nílu ìbàdàn lásìkò tí wọ́n ńsọ̀rọ̀ lórí pàtàkì ìgbélárugẹ ètò mọ́ọ̀kọ mọ́ọ̀kà fún dàgbàsókè ilẹ̀yí.

Nínú èro rẹ̀, ọ̀jọ̀gbọ́n ètò ẹ̀kọ́ mọ́ọ̀kọ mọ́ọ̀kà lẹ́ka ẹ̀kọ alágbelegboye(Distance Learning) ní fásitì ìbàdàn, Rashid Aderinoye sàlàyé pé owó tí wọ́n ya sọtọ fétò ẹkọ kere jọjọ.

Ẹwẹ nínú ọ̀rọ̀ ọ̀hún kan náà, ọ̀jọ̀gbọ́n ní nílé ẹ̀kọ́ ọ̀hún Kester Ojokheter pepe fún àtúngbéyẹ̀wò abala kẹrin ìlànà áàtẹle lórí ètò ẹ̀kọ́.

Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n lẹ́ka ètò mọ́ọ̀kọ mọ́ọ̀kà tí wọ́n bẹnu àtẹ́ lu bí àwọn tí ó lọ sílé ẹ̀kọ́ se ń pọ̀si, sàlàyé pé gbígbọn wọ́ sí ẹ̀náwó ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ àti ìpèsè oun èlò ìmọ̀ ẹ̀rọ ayálujára láwọn ilé ẹ̀kọ́ yóò se àlékùn ètò mọ́ọ̀kọ mọ́ọ̀kà nílẹ̀ Nàijírìa.

Famakin/Olaọpa   

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *