Yoruba

Ilé Isẹ́ Radio Nigeria Fẹ́ẹ̀ Kí Àlékún Bá Ìdánilẹ̀kọ Fáwọn Òsìsẹ́ Rẹ̀

Ilé isẹ́ Radio Nigeria, FRCN, ti tẹnumọ́ pàtàkì sísàmúlò àsà wíwo àwòkọ́se òun síse ìdánilẹ́kọ lábẹ́lé kólè fi kún akitiyan àwọn òsìsẹ́ kí wọ́n le jáfáfá si lẹ́nu isẹ́.

Ọga àgbà lẹ́ka ìròyìn àti ọ̀rọ̀ tónlọ fúnlé isẹ́ Radio Nigeria, ẹkùn Ìbàdàn Alàgbà Adenrele Ajisefinni ló sọ̀rọ̀ náà nílu Abẹokuta, ìpínlẹ̀ Ògùn lásìkò ètò ìdánilẹ́kọ fáwọn atúnmọ̀ òsìsẹ́ min nílé isẹ́ Radio Paramount F.M.

Adelé ọ̀gá àgbà ilé isẹ́ Radio Nigeria ẹkùn Ìbàdàn, Arábìnrin Bọlanle Owoyẹmi àti Alàgbà Adenrele wá rọ àwọn òsìsẹ́ láti jìnà sí ìwà ìaní ìkóraẹni nijanu, pẹ̀lú síse àmúlò jíjẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ kólè bá ǹkan táwọn èyàn ń réti mú pẹ̀lú mímú àlékún bá owó tón wọlé lábẹ́lé fúnlé isẹ́ náà.

Alàgbà Ajisefinni fẹ̀mín ìdánilójú rẹ̀ hàn pé àwọn akópa níbi ètò náà yóò jànfàní ìmọ̀ tókún pẹ̀lú ètò ìdánilẹ́kọ ọhun tí yóò si mú ìdàgbàsókè bá àwọn olùgbọ́.

Ẹwẹ nígbà tón sísọ lójú ètò náà, ọ̀gá àgbà ilé isẹ́ Paramount FM, Alhaji Adeniyi Ọdekunle tó gbórínyì fún ìgbìmọ̀ ìsàkóso ilé isẹ́ Radio Nigeria fún ètò ọ̀hún, fẹ́ kílé isẹ́ náà gbọn wọ́ sí ìsọwọ sisẹ́ àwọn òsìsẹ́.

Nínú ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ọ̀gá lẹ́ka ìròyìn Arábìnrin Olurẹmi Olugbenro àti ọ̀gá lẹ́ka ètò gbogbo nílé isẹ́ náà, ọ̀gbẹ́ni Dapọ Oyekanmi wá rọ àwọn akópa láti sàmúlò ètò ìdánilẹ́kọ náà fún kíkọ́ ǹkan tuntun.

Lara Ayọade/Ayodele Ọlaọpa

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *