Àjọ tó mójútó fífi era sọwọ́ sókè òkun NEPC, ti tẹnumọ́ pàtàkì kí àwọn tón se okòòwò fífi ẹrù sọwọ́ sílẹ̀ òkèèrè se gbogbo ǹkan tó tọ́ fún fífi àwọn ọjà wọn sọwọ́ sí ọjà àgbáyé.

Gẹ́gẹ́bí ọ̀gá àgbà àjọ ọ̀hún, Ọ̀gbẹ́ni Olusẹgun Awolọwọ sewí, àjọ NEPC, ló sàpèjúwe àwọn ìlànà fífi ǹkan sọwọ́ àti àkójọpọ̀ ìwé toyẹ gẹ́gẹ́bí ìpèníjà tón kojú fífi ọjà sọwọ́ sílẹ̀ òkèèrè pẹ̀lú àlàyé pé oseese kí ìpèníjà náà pagidínà okoowo sílẹ̀ òkèèrè.

Ọgbẹni Awolọwọ tí ọ̀gá àgbà lẹ́ka tón rísí ìròyìn ọrọ̀ ajé, Arábìnrin Evelyn Obidike sojú fún sàlàyé pé àfojúsùn àjọ náà ní láti wójùtú sí ọ̀rọ̀ náà àtàwọn ìpèníjà tón mú fàsáyìn bá okòòwò sílẹ̀ òkòòrè.

Ẹwẹ nínú ọ̀rọ̀ alámojútó àjọ ọ̀hún fẹ́kí ìwọ́ orun gusu ilẹ̀yí, Ọ̀gbẹ́ni Samuel Oyeyipo ti igbákejì rẹ̀, Arábìnrin Francisca Odega sojúfún, sàlàyé pé, kí okòòwò sílẹ̀ òkèèrè tó lé sọ èso rere, ógbodọ ma tele ìlànà àkọsílẹ̀ tọtọ, kole mú ìgbélárúgẹ bá ọ̀rọ̀ ajé ilẹ̀ òkèèrè fúnlẹ̀yí.

Lara Ayọade/Ayodele Ọlaọpa

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *