Yoruba

Ijoba Ile Nigeria Pe Fun Ayipada Rere Fun Eka Eto Idajo

Igbakeji Aare ile yi, Ojogbon Yemi Osinbajo ti ro awon alamojuto eka ofin lawon ipinle pe I won maa kaare ninu ojuse won lona ati mu ayipada rere ba eka eto idajo ile yi.

Igbakeji Aare Osinbajo sipaya oro yi lasiko to n gbalejo awon alakoso eto idajo mefa lati apa Guusu iwo oorun ile yi.

Saaju ni won ti salaye nipa idagbasoke to ti ba liana atunto eka eto idajo nipinle kowa won.

Awon alakoso eto idajo to ba igbakeji Aare lalejoo ni Alakoso eto idajo nipinle Ekiti saaju won pelu awon akegbe re latawon ipinl bii Eko, Ondo, Oyo, Ogun ati ipinle Osun.

Igbakeji Aare ile yi gbosuba fun awon alakoso eto idajo nss nips akitiyan won nipinle koowa lori igbese atunto eka eto idajo.

O salaye wipe o se pataki fun gbogbo ipinle lati rii daju pe won ko fie to idajo ododo fale.

Ninu oro otooto won, won toka si igbese atunto to ti waye nipinle koowa bii wiwa ona abayo lati tete yanju ede aide, gbogbo idajo lakoko to ye, eto ironulagbara fawon osise, eka eto idajo sise amulo ero ayara bi asa ati ipese inkan amayederun lapapo ni eka eto idajo nipinle kowa won.

 Tawakalit Abiola/Babatunde Salawudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *