Yoruba

Gomina Ipinle Osun Gbawon Odo Niyanju Lori Agbega Asa

Gomina Ipinle Osun, Ogbeni Adegboyega Oyetola, ti soo di mimo pe igbese to nipon gbodo waye nidi ati rii daju pe ajosepo to loorin wa laarin awon odo ile yi ati pe won gbodo yago fun iyapa.

Gomina soro yi di mimo lasiko to n side eto ere idaraya ati igbaga asa eyi ti ajo agunbaniro se agbekale re ni elekunjekun eyi ti nwaye nibudo ifinimole ajo naa nipinle Osun.

O salaye wi pe, ile Nigeria to se akojopo awon eya ati asa lolokan o jokan lo nilo ati maa ko awon odo papo fun agbega ile yi.

Gomina eni ti alakoso oro odo ati ere idaraya nipinle Osun, Ogbeni Yemi Lawal soju fun sapejuwe asa ati ere idaraya gege bi ohun elo Pataki fun aseyori.

Gomina Oyetola ro awon akopa pe ki won ri eto naa koja itakangbon bi ko se anfaani lati gbe asa won laruge.

Ninu oro tie, oludari ajo agunbaniro lekun guusu iwoorun, Arabinrin Funmilayo Akin-moses, o salaye wipe odun marunlelogbon seyin ni won se agbekale eto naa lati fi se awari awon to be ni ebun atinude won awon agunbaniro lona ti agbega yoo tun fib a isokan ile yi.

Adenitan Akinola/Babatunde Salaudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *