Àjọ tón rísí ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì nílẹ̀ yíì, NEMA, àti tìpínlẹ̀ Èkó LASEMA, ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, àwọn èèyàn tó ti dolóògbe níbi ìsẹ̀lẹ̀ ilé alágà mọ́kànlélógún tó wà nípinlẹ̀ Èkó, jẹ́ méjìlélógún báyíì.

Gẹ́gẹ́ báwọn àjọ méjàjì se fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, méjì lókú àwọn tíwọn sì rí yọ láfẹ̀mójú òní.

Sáàjú nìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti sọpé, òun yóò san gbogbo owó ìtọ́jú àwọn èèyàn tórí bákóyọ nínú ìsẹ̀lẹ̀ burúkú náà.

Gómìnà Babajide Sanwo-Olu ti wá pàsẹ pé kí alábojútó àgbà tón bójútó ọ̀rọ̀ ilé kíkọ́ nípinlẹ̀ náà, Ọ̀gbẹ́ni Gbọlahan Oki lọ rọ́kún ńlé.

Nígbà tó ńfèsì lórí ọ̀rọ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni Oki, sàlàyé pé àjà mẹ́ẹ̀dógun péré niwọ́n fọwọ́sí pé kẹ́ni tónilé kọ́ sórí ilẹ̀ náà, kó tó dipé ó lọ kọ́ mọ́kànlélógún.

Net/Fọlakẹmi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *