Aya igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, Bọlanle Ọlaniyan tún ti tẹnumọ ìdí tó fi sepàtàkì káwọn èèyàn máà lọ fáyẹ̀wò ọyàn wọn, kíwọ́n lè ba tètè tọ́jú èyíkèyí ohun tí wan bá kẹ́fín níbẹ̀, kó tó pẹ́jù.

Ọjọgbọn Ọlaniyan tó fìdí èyí múlẹ̀ níbi ètò ìpolongo kan, lọfisi aya Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pẹ̀lú àjọsepọ̀ ẹgbẹ́ tón rísí ọ̀rọ̀ jẹjẹrẹ ọyàn láwùjọ dìjọ gbékalẹ̀ niwọ́n pe àkórí rẹ̀ ní pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ òpin yóò débá jẹjẹrẹ ọyàn.

Ó wá gbàwọn obìnrin níyànjú láti máà se rí jẹjẹrẹ ọyàn bi ẹ̀mi tó ti gba ọjọ́ ikú rẹ̀, pẹ̀lú àtọ́kasí béèyan bánlọ fún àyẹ̀wò ọyàn lórekóòre, yóò mádinkù bá a dẹbi to lapere.

Áàrẹ ẹgbẹ́ àwọn obìnrin tíwọ́n jẹ́ akọ́sẹ́ mọsẹ́, onímọ̀ ìsègùn òyìnbó, MWAN, Dókítà Lilian Otọlorin sàlàyé pé, àwọn ikọ̀ tón sàtìlẹyìn fún dídènà àisàn jẹjẹrẹ ti wa káàkiri orílẹ̀dè yíì, láti máà pèsè fami àwọn tàisan jẹjẹrẹ ọyàn ńbá fínra tófimọ́ àwọn ẹbi.

Ètò ìwọ́de ìtanijí náà lórí dídènà àisàn jẹjẹrẹ ọyàn tó wáyé lólúlesẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Secretariat láwọn òsìsẹ́ elétò ìlera péjúpésẹ̀ si.

Seyifunmi Ọlarinde/Wojuade Fọlakẹmi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *