Radio Nigeria Ibadan Zonal Station

Uplifting the People & Uniting the Nation

  • Home
  • News
  • Contact Us
  • Home
  • News
  • Contact Us
Yoruba

Ogunlọ́gọ̀ èyàn jànfàní ètò ìrónilágbára aya Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́.

By Web News 19 November 2021 924

Kòdín ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta èèyàn ló ti jànfàní ètò ìrónilágbára ti ó fisi aya Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, Arábìnrin Tamunọminini Makinde gbé kalẹ̀ nípinlẹ̀ yí.

Àwọn tó jànfàní ètò náà ni wọ́n kójọ jákèjádò ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tón bẹ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Ètò ìrónilágbára náà ló wáyé láwọn ìlú ní ẹkùn Ìbàràpá, Ogbomosọ, Ọyọ, Saki. Isẹyin, àti Ìbàdàn.

Nígbà tíwọ́n fọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú ilé isẹ́ Radio Nigeria, alága ìjọba ìbílẹ̀ Ìsẹ́yìn àti tìjọba ìbílẹ̀ àrìwà òbàdàn, ọ̀gbẹ́ni Osuọlale Abilawọn àti ọ̀gbẹ́ni Saheed Ọladayọ sàlàyé pé ètò náà ló bọ sákíkò pẹ̀lú àlàyé pé yóò sàyípadà ìgbé aye àwọn tó jànfàní ẹ̀ si rere.

Ẹwẹ, alábojútó fọ́rọ̀ àwọn ìjóba ìbílẹ̀ àtọ̀rọ̀ oyè jíjẹ, olóyè Bayọ Lawal sọpé ètò náà wáyé nínú ìgbìyànjú àti ró àwọn èyàn ìpínlẹ̀ yi lágbára ní síse ń tẹ́lẹ̀.

Ẹni tó sàgbékalẹ̀ ètò náà, títúnse aya Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, arábìnrin Makinde tó sàgbékalẹ̀ àwọn ohun èlò náà fáwọn tọ́rọkàn sàlàyé pé àwọn obìnrin le di gbajugbaja olokooro àti olùgbanisísẹ́ pẹ̀lú àfọnkànsì, pẹ̀lú ríró wọn lórí lilo àwọn ohun èlò náà lọ́nà tó wuyì.

Ètò ọ̀hún tí àwọn èkàn lára àwọn alásẹ ìjọba ti wa níkàlẹ̀ ni wọn ti pin ero iransọ, ero iseranloge, agolo afẹfẹ gáàsi àti àwọn ǹkan min.

Ọkarẹ/Ọlaọpa

Tags: anfaani aya Gomina Makinde Ironilagbara ogunlogo

Post navigation

Previous Previous post:

Ìjọba àpapọ̀ lu ilẹ̀ Amẹrica lọ́gọ ẹnu lórí ìrànwọ́ fún ìgbógun ti ìgbésùmọ̀mí

Next Next post:

Governor Makinde Visits Yesterday’s Tanker Explosion Scene


Recent Posts

  • UK Prepares Ships for Possible Mediterranean Deployment
  • Tinubu, NIS DG, Mourn Legendary Festus Onigbinde
  • Erdogan Warns Iran over Turkish Airspace Violations
  • Agric Ministry Urges Farmers to Follow Weather Forecasts
  • Festus Onigbinde and His Enduring Football Legacy

You can reach us via phone or email.

+2348055434968
+2347065299766
+2348033611474

[email protected]
[email protected]

Federal Radio Corporation of Nigeria, Broadcasting House,
Oba-Adebimpe Road, P.M.B. 5003, Dugbe, Ibadan, Nigeria.

 

Lagos Liaison Office, Radio Nigeria Ikoyi, Headquarters Building
+2348036960419
+2348039653024

Copyright © 2017 News247 All Rights Reserved.
Verified by ExactMetrics