Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ lu ilẹ̀ Amẹrica lọ́gọ ẹnu lórí ìrànwọ́ fún ìgbógun ti ìgbésùmọ̀mí

Àarẹ Muhamadu Buhari ti fẹ̀mí ìmoore hàn sí àwọn alásẹ ilẹ̀ Amẹrica lórí bí wọ́n se gba ilẹ̀ Nàijírìa láàye láti ra ohun ìjagun fún gbígbógun ti ìgbésùmọ̀mí tó fimọ́ ètò ìdánilẹ̀kọ tíwọ́n se fáwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Nàijírìa.

Àarẹ Buhari sọ̀rọ̀ náà nílu Abuja lásìkò tón gbàléjò akọ̀wé ìjọba ilẹ̀ Amẹrica, ọ̀gbẹ́ni Anthony Blinker.

Àarẹ sàlàyé pé, ìrànwọ́ tílẹ̀ yí tín rí gbà ti jẹ́ kin ǹkan padàbọ̀ sípò lẹ́kùn ìlà orun àríwá àarẹ tún sàlàyé pé ilẹ̀ Nàijírìa àtàwọn alámulegbe rẹ̀ ni wọ́n tín gbé pẹ̀lú ipa ti ko da tó ti àyípadà ijú ọjọ́ fa, eléyi tó fa bí alagbalugbu omi Lake Chad se kun ju bó se wà tẹ́lẹ̀ lọ tó sin ni ipa ti kó da lara miliọnu lanà ọgbọ̀n èyàn làwọn orílẹ̀èdè lẹ́kùn Lake Chad.

Àarẹ sàlàyé pé ọ̀rọ̀ náà lón fa bí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ se ń sá kúrò lẹ́kùn náà ló sókè òkun.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ni ọ̀gbẹ́ni Blinker ti wá sọpé ilẹ̀ Amẹrica àti ilẹ̀ Nàijírìa lóní ìpèníjà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí àisètò àbò pẹ̀lú síse ìlérí lórí wíwá ojútu sáwọn ìpèníjà náà.

Ayodele Ọlaọpa

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *