Yoruba

Àjọ INEC Fẹ́ Sàmúlò Ọ̀nà Ìgbàlódé Ètò Ìdìbò

Àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ yíì INEC, ní òun ti sàgbékalẹ̀ ọ̀nà ìgbàlódé nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ láti fòpin sí màgòmágó ìbò àti wípé wọ́n ti ńsisẹpọ pẹ̀lú àwọn àjọ elétò ààbò, àjọ tó ńrísí ìwà àjẹbánu àti èyítí ó ńgbógunti oogun olóró NDLEA, láti fojú ẹnikẹ́ni tó bá lọ́wọ́ nínú rira ìbò àti jíjí àpóótí ìbò gbé káta òfin.

Ọga àgbà àjọ INEC, nípinlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀mọ̀wé Mutiu Agboke ẹnití ó sọ̀rọ̀ yí níbi àpàdé àwọn tọrọkan lẹ́kùn Ọ̀yọ́/Ogbomọsọ èyítí ó wáyé ní gbọ̀ngàn Àtìbà nílu ọ̀yọ́ tẹnumọ wípé iforikọsilẹ olùdìbò ńlọ lọ́wọ́ láwọn ọ́fìsi wọn tó wà níjọba ìbílẹ̀ káàkiri ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́.

Àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ yí, INEC, ti ní òun ńgbèrò àti pín iforukosilẹ olùdìbò tó ńlọ lọ́wọ́ sáwọn ibùdó ìdìbò gbogbo sáàjú ètò ìdìbò gbogbogbò tọdún 2023.

Elizabeth Idogbe/Aminat Ajibike

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *