Sáàjú gbèdéke ọjọ́ kini osù kejìlá, fún gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára àrùn Covid-19 fáwọn òsìsẹ́ ìjọba, ìjọba àpapọ̀ ti sèkìlọ̀ fáwọn òsìsẹ́ tó fẹran isẹ́ wọn láti lọ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára.

Pẹ̀lú onírunru ẹrọ tón tẹlẹ ọ̀rọ̀ yíì, èyító jẹ́ kíkéde lósù kẹsan, ìjọba ni ìgbésẹ̀ náà wáàyé níbamu pẹ̀lú ifẹ̀ àwọn èèyàn ilẹ̀ Nàojírìa.

Nígbà tóun sọ̀rọ̀ nílu Abuja, lásìkò tó ńsọ̀rọ̀ lórí bínkansenlọ lórí abẹ́rẹ́ àjẹsára covid-19, alákoso fétò ìlera, Dókítà Osagie Ehanire, wóòye pé pípan abẹ́rẹ́ àjẹsára covid-19 ní dandan sepàtàkì, torípé ilẹ̀ yíì kole wáà lẹ́yìn nidi ìgbóguntì àrùn.

Ó wá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, abẹ́rẹ́ àjẹsára covid-19 wá nlẹ fún gbigba nilẹ yíì, tósì gbawọn tikoti gba abẹ́rẹ́ níyànjú láti se bẹ gẹ́gẹ́.

Elizabeth Idogbe/Aminat Ajibike

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *