Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀la lọ, ijoba apapo yoo fi òfin de ọkọ̀ Òfurufú Wiwo orile-ede yii wá láti àwọn orileede bii Canada, United Kingdom, àti Saudi Arebia. 

Alakoso ètò irinna Òfurufú nílè yíì Hadi Síríà lo kéde ìgbése yí nilu Èkó pẹ̀lú àlàyé wípé, igbese yí kò sẹyìn bí àwọn orileede náà se fofin de ọkọ̀ ofurufu ilé yí pé kò gbọ́dọ̀ wo orile-ede wọn nítorí ajakale àrùn covid tuntun tí wọ́n ń pè ní Omicron tó tún gbòde.

Ogbeni Sírika ṣàlàyé wípé ìjọba Ààrẹ Muhammadu Buhari yóò máa tópinpin àwọn orileede meteeta nítorí ajakale àrùn burúkú náà.

Ó tenumo pé táwọn orile-ede náà bá n fojú sí orile-ede yii lára, kò jẹ ki wón je ki ọkọ ofurufu wọ́n fo wo ile yii fún eto ọrọ ajé. 

Ogbeni Sírika wá rawo ẹ̀bẹ̀ sáwọn ọmọ ilẹ̀ yí tó bá ń gbèrò láti lọ sáwọn orile-ede tọrọ kàn pé kí wọ́n fowó wọnú àti pé torí ààbò ile yi ni ìgbése náà wà fún.

Net / Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *