Oludamoran pataki fun aare Muhammadu Buhari lori ona lati mu iderun ba eto okowo omowe Jumoke Oduwole ti kesi awon omo ile yi pe ki won maa lo eroja aso to ba je ojulowo ti won n pese lorileede yi.

Omowe oduwole pepe yi lasiko abewo enu ise to se si gomina ipinle ogun, omooba Dapo Abiodun .

Oludamoran pataki fun aare salaye wi pe ijoba apapo yoo maa mu iwuri wa fawon ileese abele to n pese aso lona ti won yio fi le maa fi sowo sile okeere.

Nigba to n fesi, Gomina ipinle ogun  omooba Dapo Abiodun eni ti akowe ijoba ipinle naa, ogbeni Tokunbo Alabi  sojufun gbosuba funjoba apapo lori igbese ipese aso adire nipinle ogun.

Gomina Abiodun tenumo pe igbiyanju ijoba apapo naa ni yoo se atileyin fun akitiyan ijoba  re lori agbega aso adire fun lilo awujo agbaye.

Adesida/ Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *