Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀sun, ọ̀gbẹ́ni Adegboyega Oyetọla, ti síjú áànu wo àwọn ẹlẹ́wọ̀n mọ́kànlá tó wá láwọn ibùdó àtúnse ìlú Ilésà àti Ilé-Ifẹ, tó sì dáwọn sílẹ̀.

Gómìnà Oyetọla tó sanwó ìtanràn àwọn ẹlẹ́wọ̀n mọ́kànla náà lákokò àyẹ̀wò tó gbópọn lórí ẹ̀sùn wọn, sọ pé, ìgbésẹ̀ náà wáyé láti mú àdínkù bá báwọn ibùdó àtúnse náà seń kún lákunfàya.

Gómìnà Oyetọla ẹnití agbẹjọ́rò àgbà títún se alákoso fétò ìdájọ́ nípinlẹ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni Fẹmi Akande sojú fún, rọ àwọn ẹlẹ́wọn tíwọ́n rí ìtúsílẹ̀ wọn gbà látọ̀dọ̀ Gómìnà ọ̀hún, láti máà se padà sẹ́sẹ̀ áàrọ̀ wọn, èyí tó tún lè dáwọn padà síbùdò àtúnse náà.

Nígbà tón sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìtúsílẹ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà, igbákejì olùdarí ibùdó àtúnse nílu Ilésà, nípinlẹ̀ Ọsun, ọ̀gbẹ́ni Olosọla Amọran, gbóríyìn fún Gómìnà Oyetọla fún bó se tún mádikùn bá iye àwọn ẹlẹ́wọ̀n tón bẹ níbùdó ọ̀hún.

Folakemi Wojuade   

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *