Ìjọba àpapọ̀ ti fagilé sísàmúlò ìwé àbọ̀ láti mọ bí òsìsẹ́ ọba seń sisẹ́ sí lọ́dọdún èyí tí wọ́n ń dape lédè gẹ́ẹ̀si ni Annual Performance Evaluation Report Aper.

Olórí òsìsẹ́ nílẹ̀ yí Ọmọwe Fọlasade Yẹmi Ẹsan ló jẹ́ kọ́rọ̀ yí di mímọ̀ nílu Abuja.

Ọmọwe Yẹmi-Ẹsan sọ pé ìjọba ti se ìfilọ́lẹ̀ ìlànà ọ̀tun míran tí wọ́n pè lédè gẹ́ẹ̀si ni Performance Management System PMS.

Gẹ́gẹ́bótiwí, ìlànà PMS, ni wọ́n yo ma se lójú òpó ẹ̀rọ ayélujára fún gbogbo òsìsẹ́ ìjọba.

Olórí òsìsẹ́ wá fikun pé, ọ́fìsì rẹ tin ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú àwọn tọ́rọkàn lọ́nà tí ètò ọ̀hún yo fi kẹ́sẹjári yíká orílẹ̀ èdè yí.

Ajibikẹ/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *